Easy Read Guide Yoruba Programme.pdf | |
File Size: | 1201 kb |
File Type: |

yoruba_programme_audio_file.mp3 | |
File Size: | 653 kb |
File Type: | mp3 |
Tuesday 25 August
6pm GMT + 1
Taiwo Aiyedogbon
Aaye (Space),
2020
Live Performance
Mo nife lati mu ayika pelu isepo Ewi, nibi ti awon akole ti o jomo si oro, omo, iya, baba, agbo ile, awon ibeji, Oba, asa, ile Yoruba ati die ninu awon oro to jemo ise ile Yoruba nipase Ewi.
Mofe se igbejade Aaye, fun wakati kan ogbon iseju sise ni pelu egbe awon odo okunrin, bi mo se n reti lati fa edun, ipeni ati ise lait owo awon eniyan owujo ati ibomi.
--------
I am interested in creating an atmosphere that engages with Yoruba poetry, where topics relating to wealth, children, mother, father, household, twins, kings, traditions, Yoruba land and some other words relating to the culture of Yoruba land are discussed through Yoruba poetry.
I will be presenting Aaye (Space), an hour and thirty minutes live performance with a group of young men, as I look forward to drawing out emotion, provocations and reactions from my immediate audience and beyond.

Thursday 27 August
12pm GMT + 1
Aderemi Adegbite
ABD Olówe
móhùnmáwòrán
2020
Yorùbá gẹ́gẹ́ bí èdè ìbílẹ̀ ní ẹwà a rẹ̀ nínú àmì ohùn tí ó ń fi ìyàtọ̀ hàn láàárín ọ̀rọ̀ kan sí ìkejì. Dò Re Mí (\_/) gẹ́gẹ́ bíi àmì ohùn lè yí ìtumọ̀ padà tí kò bá sí lórí ọ̀rọ̀ tàbí tí a bá ṣìí lò. ABD gbé ìfààmí sí orí ọ̀rọ̀ yẹ̀wò àti bí ó ṣe kan bí ọ̀rọ̀ ṣe ń dún. Dídún ọ̀rọ̀ ni ibi tí ń ó ti bẹ̀rẹ̀ nínú móhùnmáwòrán yí, n ó sì lo àgbéyẹ̀wò àwọn ohun tí mo ti tọ́jú tí ó níí ṣe pẹ̀lú bí a ṣe ń to ọ̀rọ̀ papọ̀.
----
Aderemi Adegbite
ABD Olowe
Video
2020
Yoruba as a vernacular has its beauty in its tonal punctuations that create rhythmic tunes. Do Rẹ Mi (\ _ /) as the tonal marks could give twisted meaning when missing or wrongly applied. ABD Olowe interrogates the application of tonal marks and the internal rhyme of its poetics. Tonality of the phonetics is my point of departure in this video through the use of both archival footage in response to the phonetics and grammar construction.

Saturday 29 August
12pm GMT + 1
Jelili Atiku
Dìde, Dúró, Fara balẹ̀ fún Ògìrììyàndá
2020
Eré yí ní ètùtù fún ìwẹ̀mọ́ nínú, àtúntò fún àwọn nǹkan ìṣẹ̀dálẹ̀ láti túbọ̀ fún ẹ̀dá ní okun, àlàáfíà àti agbára. Ó ń ṣe ìgbélékè Odù Ifá, Èjìogbè, tí ó sọ wípé; Atẹ́ni árà Awo òkun, Làá pe ajé, Atẹ́ni-lárà Awo ọ̀sà, Làá pe aya Atẹ́ni lárà Awo atan omi, Làá pe ọmọ tuntun jòjòló; Orí mi àpére, Àyà mi àfobì kàn.
'Ìkì Ifá
Ifá ní
Rúkú rúkú rúkú,
Womu womu womu,
Tàbí rí tàbí rí wọ̀mu;
Dìfa fún Fàboyékẹ̀,
Ti ṣe ọmọewé nílé Àlàdò
Lọjọ t'ara n ṣé kúgẹ̀, t'ara n ṣé kúgẹ̀,
Ọrùnmìla Ògìrììyàndá, Ifá
Má mà jẹ̀ kí a mú ará kúgẹ̀ kúgẹ̀ sìn ẹ o.
Àwa tí dì ewé Agbòdànyìn,
Àwa tí dì Ìgi Ìrosùn,
Àrùn kán, àrùn kàn,
Tó ṣeé wá làlẹ aanà,
Ìpẹ̀pẹ̀ là fi ṣé, Agbọ̀n là f'gbọ̀n dánu;
Akìkà ki ṣé bẹ k'òdubúlẹ̀ k'okù o,
Pọ̀nrángàndàn ká ji o,
Ẹ̀là k'a malà pọ̀nrángàndàn.
----
Jelili Atiku
Stand, Wait, Listen for Ògìrììyàndá
2020
The performance consists of ritual of cleansing, re-alignment with the energies of nature to reinvigorate personal human body, health and mental strength. It references Odu Ifa, Èjìogbè, which says, Atẹ́ni árà Awo òkun, Làá pe ajé, Atẹ́ni-lárà Awo ọ̀ṣà, Làá pe aya Atẹ́ni lárà Awo atan omi, Làá pe ọmọ tuntun jòjòló; Orí mi àpére, Àyà mi àfobì kàn.
(Ifá sacred poetry) used in the performance:
Ifá said Rúkú rúkú rúkú
Womu womu womu
Tàbí rí tàbí rí wọ̀mu;
made ifa divine consultation for Fàboyékẹ̀ Whom was young in Alado’s house,
On the day he/she was feeling unhealthy
Ọrùnmìla Ògìrììyàndá (who people rush/troop to in order to choose their destiny), Ifá, don’t let us
worship you with unhealthily body
We have become Agbòdànyìn leaf,
We have become Ìrosùn tree,
The disease, the illness
That struck us last night
We have made it into palm tree fiber,
we have cleared it away with basket,
Pangolin does not just lie down and die like that
Pọ̀nrángàndàn let us wake (or rise) oo
Ẹ̀là let us succeed (or wake/rise) pọ̀nrángàndàn.
Sunday 29 August
2pm GMT + 1
Àsìkò Oúnjẹ Ṣíṣe
ÀMÀLÀ, EWÉDÚ ÀTI OMI ỌBẸ̀
Ewédú jẹ́ ewébẹ̀ aláwọ̀ ewé tí ó ṣe é jẹ, tí a sábà máa ń sè, tí yóò sì di ọbẹ̀ yíyọ̀ tí ó dùn láti jẹ. Orúkọ sáyẹ́ǹsì ewédú ni corchorus olitorius.
Àmàlà jẹ́ èlùbọ́ iṣu tí a mú jáde láti ara èèpo/ara iṣu lẹ́yìn tí a ti sá a tí ó ti gbẹ dáradára, tí a sì lọ̀ ọ́ lúbúlúbú.
ÀLÀYÉ BÍ A Ó TI WÁ OÚNJẸ NÁÀ
Oúnjẹ tí a ó sè ní gbangba ìta ni, àwọn tí orúkọ wọ́n wà ní òkè yìí yóò wà ní àrọ́wọ́tó láti ṣe ìrànwọ́. Ó jẹ́ ohun tí ó ṣe àjèjì nítorí pé a ò dá’ná oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ní ìta gbangba rí, ó sì jẹ́ ohun tí gbogbo wọ́n ń fi ojú sọ́nà fún. Abala yí yóò jẹ́ àmúlùmálà èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Yorùbá A óò tẹ ìtumọ̀ sí orí móhùnmáwòrán yí bí ó bá ṣe ń lọ ní orí afẹ́fẹ́. Ibi tí a bá ti sọ Yorùbá, a ó kọ ẹ̀dà òyìnbó sí i, ibi tí a bá sì ti sọ òyìnbó, a ó kọ ìtumọ̀ rẹ̀ ní èdè Yorùbá.
Èèlò fún Àmàlà: Ife èlùbọ́ méjì; Ife omi mẹ́rin; Ife omi gbígbóná kan tí a gbé kalẹ̀,bóyá lílò lè kàn án.
Èèlò fún Ewédú: Ewébẹ̀ ewédú; Ìlàjì ṣíbí káún tí a ti lọ̀; Ife omi kan àti ààbọ̀; Ìjábẹ̀ tàbí ẹ̀rọ amóhunkúnná; Iyọ̀ ìsebẹ̀ kí ó lè dùn; Maggi; Ata gígún (tí a bá fẹ́); Ṣíbí mẹ́rin sí márùn-ún edé wẹ́wẹ́ tí a ti lọ̀.
Èèlò fún Omi Ọbẹ̀: Kílò ẹja kan; Tòmátì; Tàtàṣé; Atarodo; Àlùbọ́sà; Epo pupa; Maggi; Iyọ̀ ìsebẹ̀ kí ó lè dùn.
------
Cooking Session
AMALA, EWEDU ATI OMI OBE (YAM FLOUR, JUTE MALLOW WITH STEW)
Ewedu is a green leafy edible vegetable which is often prepared into a delicious slimy soup. Ewedu is botanically known as corchorus olitorius.
Amala is a yam flour gotten from yam peels/skin that is well sun dried and grinded into flour.
DESCRIPTION OF THE COOKING SESSION
It is going to be an outdoor cooking where the people listed above will be available to assist. It is definitely an unusual event because we never cook outdoors and they are all looking forward to it. The session will be code mixed and code switched in Yoruba and English. The video will be subtitled both in Yoruba and English, that is, where anyone speaks Yoruba it will be subtitled in English and vice versa.
Ingredients for Amala: 2 cups of Yam Flour (Elubo) ; 4 cups of water ; 1 cup of Hot water reserved
Ingredients for Ewedu: Ewedu leaves ; ½ teaspoon of powdered potash ; 1.5 cups of water ; Ewedu broom chopper/ blender ; Salt to taste ; Maggi ; Chili pepper to taste (optional) ; 4-5 spoons of grinded crayfish
Ingredients for Omi Obe (Stew): 1 kilo of Titus Fish ; Fresh Tomato ; Tatashe (red bell pepper) ; Scotch Bonnet (fresh pepper, ata rodo) ; Onions ; Palm oil ; Seasoning cubes, Salt.